Àwòránhùn ètò àgbésáfẹ́fẹ́ kan láti ọwọ́ News Central TV tí ń tàn káàkiri orí ẹ̀rọ-ayélujára pẹ̀lú àhesọ pé ilé-iṣẹ́ ìfọpo Dangote sọ pé òun yóò máa ta epo ọkọ̀ (PMS) tí a mọ̀ sí ‘epobẹntiró‘ lábẹ́lé si àwọn ọjà Nigeria ní owó dọ́là.
Àwòránhùn náà, tí @instablog9ja gbé jade lórí ìkànnì X, pẹ̀lú àhesọ náà ti tàn káàkiri bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn aṣàmúlò X mìíràn ti pín in.
ÀBÁJÁDE ÌWÁDÌÍ WA: ÌSINILỌ́NÀ NÍ ÀHESỌ YÌÍ
Àwọn ìwádìí láti ọwọ́ ilé-iṣẹ́ FactCheckHub fi hàn pé àwòrán tí ó ń tàn ká náà ni News Central TV fi sórí ẹ̀rọ ayélujára níọjọ 26, Oṣù Kẹ̀sán-án, ọdun 2023, atipe kò ṣẹ̀ṣẹ̀ wà níta.
Nígbà tí ó ń fèsì sí àhesọ náà, Ukadike Chinedu, agbenusọ fúnàwọn Independent Petroleum Marketers Association of Nigeria (IPMAN) nínú ìròyìn kan tí wọ́n gbé jáde ninu ìwéìròyìn Punch kan ní òṣù kìíní, ọdun 2024 tako àhesọ náà.
“Owó tí òfin mọ̀ ní Nigeria ni náírà. Náírà ni símẹ́ńtì tí Dangote ń tà, kì í ṣe dọ́là. Sìpàgẹ́tì àti àwọn ọjà pàtàkì mìíràn tí ó ń tà náírà ni ó ń tà wọ́n pẹ̀lú. Nítorí náà, kín ló dé tí èèyàn yóò ronú pé yóò ta epo bentiró ní dọ́là?,” Chinedu sọ èyí.
Nígbà tí a kàn sí i, Anthony Chiejina, agbenusọ fun ilé-iṣẹ́ Dangote Group, ṣe àpèjúwe àwòránhùn náà pẹ̀lú àhesọ tí ó ń tàn ká bí “ìròyìn ayédèrú”.