Ajìjàgbara Biafra kan, Simon Ekpa, ti ṣe àgbéjáde àwọn àwòrán tí ó ń ṣàfihàn àwọn ohun ìjà ogun pẹ̀lú àhesọ pé àwọn ọmọ ogun Biafra Resistance Fighter (BRF) gbà wọ́n lásìkò ìkọlù ńlá kan níbi tí wọ́n ti kọlu àwọn ọlọ́pàá Nigeria kan.
ÀBÁJÁDE ÌWÁDÌÍ WA: ÌSINILỌ́NÀ NI ÀHESỌ YÌÍ
Àwọn ìwádìí fi hàn pé àwọn àwòrán náà jẹ́ àwòrán àtijọ́ tí wọ́n lò níta ọ̀gangan ìṣẹ̀lẹ̀. A ṣe Ìwádìí Àtẹ̀yìnwá Àwòrán Google fún àwọn àwòrán náà; àwọn àbájáde wa nìwọ̀nyí:
Ìwádìí Àtẹ̀yìnwá Àwòrán Google tí a ṣe fún àwòrán kìíní fi hàn pé àwòrán náà ti wà lórí ẹ̀rọ-ayélujára láti ọdun 2022.
Ẹ̀yà àwòrán náà tẹ́lẹ̀ ni ìwé ìròyìn Leadership gbé jáde ní ọjọkọkanlelọgbọn Oṣù Kejìlá, ọdun 2022 pẹ̀lú ìròyìn tí ó ń fi hàn pé àwọn ìbọn tí wọ́n gbà lọ́wọ́ àwọn aṣẹ̀rùbàlú Boko Haram ní òpópónà Maiduguri-Damboa ní ìpínlẹ̀ Borno ni láti ọwọ́ ikọ̀ àwọn ọmọ ogun 199 Special Forces Battalion àti Civilian Joint Task Force.
Àwọn ìwádìí lórí àwòrán kejì fi hàn pé aworan náà ti wà lórí ẹ̀rọ-ayélujára láti ó kéré jù ọdun 2017.
Ìròyìn kan láti Premium Times fi hàn pé àwòrán náà ń ṣàfihàn àwọn ohun ìjà tí àwọn ọmọ ológun 202 Battalion, 21 Brigade ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Mobile Strike Team (MST) gbà padà ní ìpínlẹ̀ Borno lásìkò iṣẹ́ ológun kan tí wọ́n ṣe ìfilọ́lẹ̀ tako àwọn aṣẹ̀rùbàlú Boko Haram ní Oṣù Kọkànlá ọdun 2017.
Àwọn ìwádìí síwájú sí i fi hàn pé àwòrán kẹta ti wà lórí ẹ̀rọ-ayélujára láti ọdun 2018.
Ẹ̀yà ìsáájú àwòrán náà ni Air15.com, asíwájú ilé-iṣẹ́ ohun ìjà lórí ẹ̀rọ ayélujára kan, gbé jáde ní ọjọ kẹwàá, Oṣù kẹwàá, ọdun 2018 fún àwọn aṣàmúlò.
Ní ìparí, kò sí ilé-iṣẹ́ ìròyìn kankan tí ó ṣe é gbáralé tí ó ròyìn ìjà ọ̀hún láàrin ẹgbẹ́ ajìjàgbara Biafra àti àwọn òṣìṣẹ́ Ilé-iṣẹ́ Ọlọ́pàá Nigeria (NPF).