Àwòránhùn àwọn ènìyàn tí wọ́n ń dìhànràn fún búrẹ́dì ní Ìlọrin kì í ṣe laipẹ́

Share

Olùdíje nínú ẹgbẹ́ People’s Democratic Party (PDP) fún Asojú ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ní Ẹkùn Dekina/Bassa Fender fun àwọn ìdìbò gbogbogbò Nigeria ọdun 2023, Austin Okai ti fi àwòránhùn àwọn ènìyàn tí wọ́n ń dìhànràn búrẹ́dì síta pẹ̀lú àhesọ pé gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara, AbdulRahman AbdulRasaq, da búrẹ́dì sí ilẹ̀ fún àwọn ènìyàn láti máa dìhànràn lé lórí ní Ìlọrin.

ÀBÁJÁDE ÌWÁDÌÍ WA: ÌSINILỌ́NÀ NI ÈYÍ

Nígbà ile-ise FactCheckHub ṣe ìwádìí àwọn ègé ìhunàwòrán inú àwòránhùn náà lórí Ìwádìí Àtẹ̀yìnwá Àwòrán Google, àbájáde fi hàn pé àwòrán náà ti wà lórí ẹ̀rọ-ayélujáraláti Ọjọ́ Kokandinlogun, Oṣù kìíní, ọdun 2023; kì í ṣe láìpẹ́yii.

Ẹ̀yà àwòránhùn náà gígùn fi hàn pé amúrabí-obìnrin orí ìkànnì Instagram kan (Tobi Twerk), tí ó yà á, sọ pé àwòránhùn náà ń ṣàfihàn àwọn ènìyàn tí wọ́n ń dìhànràn búrẹ́dì lásìkò ìpolongo ìdìbò síwájú ìdìbò ààrẹ l’ọdun 2023 Ìlọrin, Ìpínlẹ̀ Kwara.

ìbẹ̀rẹ̀ àwòránhùn náà, amúrabí-obìnrin náà ni a rí tí ó ń pèsè ọ̀rọ̀ ìwòye bí ó ṣe ń ya àwòránhùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn tí wọ́n ń ya wọlé láti mú búrẹ́dì lára àwọn òkìtì àwọn ègé búrẹ́dì tí wọ́n pèsè fún àwọn alátìlẹ́yìn ẹgbẹ́ lásìkò ìpolongo ìdìbò ní Ìlọrin, Ìpínlẹ̀ Kwara.

YORUBA END CREDIT

Òǹkọ̀wé: Nurudeen Akewushola

Most Read

Recent Checks