Videos in compliance with YouTube’s Terms of Use and Privacy Policy
Ayédèrú ìkéde lórí rírọ́pò àwọn òṣìṣẹ́ Immigration Service fọ́n ká orí ìkànnì ìtàkurọ̀sọ WhatsApp
Ìkéde náà tí wọ́n pe àkòrí rẹ̀ ní: "Àkíyèsí Àjọ Nigeria Immigration Service Lórí Ìgbanirọ́pò gbogbogbò 2022/2023” ni a gbé jáde láti orí ẹgbẹ́ kan lórí ìkànnì ìtàkurọ̀sọ WhatsApp kan ní ọjọ́ ọ̀jọ̀ kẹwa, oṣù kejila, ọdún 2022.
Àjọ CDCFIB ti: “buwọ́lu ìbẹ̀rẹ̀ ètò igbanirọ́pò àjọ Nigeria Immigration Service ti 2022/2023”, apá kan àtẹ̀jáde náà kà bẹ́ẹ̀.
Àwọn Ìwádìí láti ọwọ́ FactCheckHub fi hàn pé IRỌ́ GBÁÀ ni àhesọ náà.
Nígbà tí a kàn sí wọn, àjọ NIS tako àhesọ akálékáko náà, tí wọ́n sì sọ pé ayédèrú ni nítorí kò sí irúfẹ́ ìkéde bẹ́ẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àjọ náà.
NIS, nínú ọ̀rọ̀ àtakò tí wọ́n fi ráńṣẹ́ sí FactCheckHub lórí WhatsApp, fún àwọn ènìyàn àwùjọ ní ìmọ̀ràn láti kọ àwọn ìròyìn bẹ́ẹ̀ tì kí wọ́n sì fi ẹjọ́ àwọn ojú òpó gbogbo tí ó ń ṣe àtúnpín ìkéde ìgbánisíṣẹ́ náà sùn.
“A sọ ọ́ ní pàtó àti láti yàgò fún iyèméjì èyíkéyìí, pé a kò gbanisíṣẹ́ nísinsìnyí báyìí," àjọ náà sọ èyí.
Lẹ́yìn àyẹ̀wò síwájú sí i, FactCheckHub ṣe àkíyèsí pé ó kéré jù ojú òpó wẹ́ẹ̀bù orísìí mẹ́rin ni ó wà lórí ayélujára tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ojú òpó iṣẹ́/ìgbaniṣíṣẹ́ Nigeria Immigration Service.
Ṣùgbọ́n sá, alukoro NIS, Anthony Akuneme, sọ pé ojú òpó wẹ́ẹ̀bù àjọ náà tí wọ́n fọwọ́ sí ni http://www.immigration.gov.ng.
YORUBA END CREDITS
Òǹkọ̀wé: Raji Olatunji
Atúmọ̀-èdè: Simeon Oluwole Onaolapo
Oníròyìn: Adéjọkẹ́ Yéwándé Olúwájọbí[+] Show More











